Oriki Owu
Omo Olowu Oduru,
Omo Ajibosin, Omo epe o ja,
Omo Otomporo lowu
Ara Owu ki ranro, awi menu kuro ntowu
Omo Ajiri Omo Ajiyin, Omo Ajilalaa eso
Omo lararohun ajile
Omo Ajibosin, omo epe o ja
Omo Lagunare nle owu
Omo Efun rojo Epo
Omo ajila
Omo Aremota n o je toju Omo,
Omo Arigbanla buwo,
Omo atewogboye,
Omo Arowo meweewa gboye nle owu
Omo Aji-fepe-sere
Eni koko la nle owu, Ogun eru lo ni,
Won n peleyun-un-oni nnkan,
Eni o tun la nle Owu, Eyi-un loji iwofa,
Won peleyun-un koni kankan,
Eni o je bi talaka tiko lowo rara, Eleyun-un lolegbeta aya,
A ba soko ija sile owu ko le bale,
Bi koba ogun eru, A ba oji iwofa,
A ba egbelegbe omo,
Omo odudu, Omo odede, Omo ogege,
Omo oriiroko, Omo alabiyamo
Omo Adelangba Abegbe yoyoyo
Baba Olowu lo solanlaju, O keni mefa re moosa,
O dirole dede, o mu rokan e wale,
Won wa nbere wipe kinni Lagbami Iregun fi marun-un e se,
Awa kuku mo n to fi marun e se.
Baba nyin pa kiki opa aiki,
Opa sise,Opa aise,
Opa Onilu, Oparinjo,
Oburin burin,O tun sonibata e kanna-n-buse loju agbo,
Omo ateni gboye; omo aboro gboye;
Omo afowomewewa gboye nle owu;
Omo a sola gbore
Omo olusandeke ajiri,
omo poye, omo alabi,
omo a jin laiye; Omo a jin lorun,
omo alajin tojin dundundun, to regbo ibara, regbo opa;
Aigbowo odo lowo osun akesan;
Tani yo wa gbowo odo lowo Owu.
Otuko toba gbowo odo lowo owu, eri a gboluware lo.
Omo Ewure wole apon, o njuru fefe
Kinni apon rije tele ti yoku nle de omo eran
Omo olode agbagba tan
Ojo nbaku e rumi rowu, e sin mi loju gbaragada.
Omo agbodigun, omo agbo dosin
Omo alagbo kan girisa to gbogbogbo
To d’oka dere nile iseri imole
Omo larowon, Omo Ajibosin,
Omo epe o ja, omo Adegoroye,
Omo Adegorite, omo ejigbara ileke
Omo ogan, omo eyin erin.
Omo owo ile o je a bere owo efun
Atoti mati omo ese bi egbe ileke
Okuta wewe la isade Ibadan,
Tani o mo p’oko tuntun lai sade owu
Omo oloko tuntun, ada osa rebete,
Omo oloko tuntun ada osa demorere
Mosa lo lopa, mowe nmese
Bi won ban nlo lorere owu, agbadabi
Ko je ka ti omo owu mo;
Nwon a sakeke wenewene,
Nwon a bu abaja mefa mefa
Awon eyan ti o gbon, awon eyan ti o moran
Won a ni abimo lowu alako nbabo.
Won a ni nsako nsabo, Ewo ni o dagba ti o se sin,
Emama dawon lohun o jare,
Loju arenije Owu o le sesin.
Enu lawu powo, Enu lawu powo,
Enu lawu podere koko nle owu,
Omo laberinjo,
Omo abebe joye,
Eyin lomo a gboro gbimo nle owu.
Owu re o, gboin gboin la nduro ti a
Owu Anthem
Owu l’a ko da o
Bi e d’ Owu
E bere wo o
Owu l’a ko da o
Bi e d’ Owu
E bere wo
Owu l’a ko da o
Bi e de’ fe
E bere wo o
Owu l’a ko da o
Bi e de ‘fe
E bere wo o
Owu l’a ko da o
Bi e de le
E ka tan wo o
Owu l’a ko da o
Bi e de le
E ka tan wo o
Owu Special Song – Owu Re O
Owu re o
Gboin gboin la’a du o tira a
Owu re o
Wara wara ni ‘re nwa a
Owu re o
Olorun orun l’o ngbe a ga
L’o nsegun fun a
L’on da wa lare
Oun l’o ngbe a’ nija
Owu re o
Awon aseni nsera won